Johanu 14:26
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
26 Ṣùgbọ́n Olùtùnú náà, Ẹ̀mí Mímọ́, ẹni tí Baba yóò rán ní orúkọ mi, òun ni yóò kọ́ yín ní ohun gbogbo, yóò sì rán yín létí ohun gbogbo tí mo ti sọ fún yín.
Read full chapter
Johanu 15:26
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
26 (A)“Ṣùgbọ́n nígbà tí Olùtùnú náà bá dé, ẹni tí èmi ó rán sí yín láti ọ̀dọ̀ Baba wá, àní Ẹ̀mí òtítọ́ nì, tí ń ti ọ̀dọ̀ Baba wá, òun náà ni yóò jẹ́rìí mi:
Read full chapter
Johanu 16:7
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
7 (A)Ṣùgbọ́n òtítọ́ ni èmi ń sọ fún yín; àǹfààní ni yóò jẹ́ fún yín bí èmi bá lọ: nítorí bí èmi kò bá lọ, Olùtùnú kì yóò tọ̀ yín wá; ṣùgbọ́n bí mo bá lọ, èmi ó rán an sí yín.
Read full chapter
1 Johanu 2:1
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
2 (A)Ẹ̀yin ọmọ mi ọ̀wọ́n, mo kọ ìwé nǹkan wọ̀nyí sí yín, kí ẹ̀yin má bà á dẹ́ṣẹ̀. Ṣùgbọ́n bí ẹnikẹ́ni bá sì dẹ́ṣẹ̀, àwa ni alágbàwí lọ́dọ̀ Baba: Jesu Kristi, olódodo nìkan.
Read full chapterCopyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.