Isaiah 63:11
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
11 (A)Lẹ́yìn náà ni àwọn ènìyàn rẹ̀ rántí ọjọ́ ìgbà n nì,
àwọn ọjọ́ Mose àti àwọn ènìyàn rẹ̀
níbo ni ẹni náà wà tí ó mú wọn la Òkun já,
pẹ̀lú olùṣọ́-àgùntàn agbo ẹran rẹ̀?
Níbo ni ẹni náà wà tí ó rán
Ẹ̀mí Mímọ́ rẹ̀ sáàrín wọn,
Sekariah 9:11
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
11 Ní tìrẹ, nítorí ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú mi pẹ̀lú rẹ,
Èmi ó dá àwọn ìgbèkùn rẹ̀ sílẹ̀ kúrò nínú ọ̀gbun.
Isaiah 55:3
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
3 (A)Tẹ́tí sílẹ̀ kí o sì wá sọ́dọ̀ mi
gbọ́ tèmi, kí ọkàn rẹ lè wà láààyè.
Èmi yóò dá májẹ̀mú ayérayé pẹ̀lú rẹ,
ìfẹ́ òtítọ́ tí mo ṣèlérí fún Dafidi.
Esekiẹli 37:26
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
26 (A)Èmi yóò dá májẹ̀mú àlàáfíà pẹ̀lú wọn, yóò sì jẹ́ májẹ̀mú títí ayérayé. Èmi yóò gbé wọn kalẹ̀, èmi yóò sì sọ wọ́n di púpọ̀ ní iye, èmi yóò sì gbé ilé mímọ́ mi kalẹ̀ ní àárín wọn títí láé.
Read full chapterCopyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.