Isaiah 61:3
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
3 àti láti pèsè fún àwọn tí inú wọn bàjẹ́ ní Sioni
láti dé wọn ládé ẹwà dípò eérú,
òróró ayọ̀ dípò ọ̀fọ̀,
àti aṣọ ìyìn dípò ìpòrúru ọkàn.
A ó sì pè wọ́n ní igi óákù òdodo,
irúgbìn Olúwa
láti fi ọláńlá rẹ̀ hàn.
Efesu 2:20-22
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
20 a sì ń gbé yín ró lórí ìpìlẹ̀ àwọn aposteli, àti àwọn wòlíì, pẹ̀lú Jesu Kristi fúnrarẹ̀ gẹ́gẹ́ bí pàtàkì òkúta igun ilé; 21 Nínú rẹ ni gbogbo ilé náà, tí a ń kọ wà papọ̀ ṣọ̀kan tí ó sì ń dàgbàsókè láti di tẹmpili mímọ́ kan nínú Olúwa: 22 Nínú rẹ̀ ni a ń gbé ẹ̀yin pẹ̀lú ró pẹ̀lú fún ibùjókòó Ọlọ́run nínú Ẹ̀mí rẹ̀.
Read full chapter
1 Peteru 2:5
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
5 Ẹ̀yin pẹ̀lú, bí òkúta ààyè, ni a kọ́ ní ilé ẹ̀mí, àlùfáà mímọ́, láti máa rú ẹbọ ẹ̀mí, tí i ṣe ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run nípa Jesu Kristi.
Read full chapterCopyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.