1 Kọrinti 2:7-10
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
7 (A)Bẹ́ẹ̀ kọ́, àwa ń sọ̀rọ̀ ọgbọ́n ti Ọlọ́run tó fi ara sin, ọgbọ́n tí ó ti fi ara pamọ́, èyí tí Ọlọ́run ti lànà sílẹ̀ ṣáájú ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé fún ògo wa. 8 (B)Èyí ti ẹnikẹ́ni nínú àwọn aláṣẹ ayé yìí kò mọ̀. Ìbá ṣe pé wọ́n mọ̀ ọ́n, wọn kì bá tún kan Olúwa ògo mọ́ àgbélébùú. 9 (C)Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé:
“Ojú kò tí ì rí,
etí kò tí í gbọ́,
kò sì ọkàn ènìyàn tí ó tí í mọ̀
ohun tí Ọlọ́run tí pèsè sílẹ̀ fún àwọn tí o fẹ́ Ẹ.”
10 (D)Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ti fi í hàn fún wa nípasẹ̀ Ẹ̀mí rẹ̀.
Ẹ̀mí á máa wádìí ohun gbogbo, kódà àwọn àṣírí Ọlọ́run tó jinlẹ̀ jùlọ.
Read full chapter
Efesu 3:3-5
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
3 bí ó ti ṣe pé nípa ìfihàn ni ó ti fi ohun ìjìnlẹ̀ hàn fún mi gẹ́gẹ́ bí mo ti kọ ṣáájú ni ṣókí, 4 Nígbà tí ẹ̀yin bá kà á, nípa èyí tí ẹ̀yin o fi lè mọ òye mi nínú ìjìnlẹ̀ Kristi. 5 Èyí tí a kò í tí ì fihàn àwọn ọmọ ènìyàn rí nínú ìran mìíràn gbogbo, bí a ti fi wọ́n hàn nísinsin yìí fún àwọn aposteli rẹ̀ mímọ́ àti àwọn wòlíì nípa Ẹ̀mí;
Read full chapter
Efesu 3:9
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
9 (A)àti láti mú kí gbogbo ènìyàn rí ohun tí iṣẹ́ ìríjú ohun ìjìnlẹ̀ náà jásí, èyí tí a ti fi pamọ́ láti ìgbà àtijọ́ nínú Ọlọ́run, ẹni tí ó dá ohun gbogbo nípa Jesu Kristi:
Read full chapter
Romu 9:18
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
18 (A)Nítorí náà ni ó ṣe ń ṣàánú fún ẹni tí ó wù ú, ẹni tí ó wù ú a sì mú ní ọkàn le.
Read full chapter
Romu 11:7
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
7 (A)Kí ha ni? Ohun tí Israẹli ń wá kiri, òun náà ni kò rí; ṣùgbọ́n àwọn ẹni àyànfẹ́ ti rí i, a sì sé àyà àwọn ìyókù le.
Read full chapter
Luku 21:24
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
24 (A)Wọn ó sì ti ojú idà ṣubú, a ó sì dìwọ́n ní ìgbèkùn lọ sí orílẹ̀-èdè gbogbo; Jerusalẹmu yóò sì di ìtẹ̀mọ́lẹ̀ lẹ́sẹ̀ àwọn aláìkọlà, títí àkókò àwọn aláìkọlà yóò fi kún.
Read full chapterCopyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.