Add parallel Print Page Options

Bíbéèrè Fún Ààmì

16 (A)Àwọn Farisi àti àwọn Sadusi wá láti dán Jesu wò. Wọ́n ní kí ó fi ààmì ńlá kan hàn àwọn ní ojú ọ̀run.

Ó dá wọn lóhùn pé, “Nígbà tí ó bá di àṣálẹ́, ẹ ó sọ pé, ‘Ìbá dára kí ojú ọ̀run pọ́n.’ Ní òwúrọ̀, ‘Ẹ̀yin yóò wí pé ọjọ́ kì yóò dára lónìí, nítorí ti ojú ọ̀run pọ́n, ó sì ṣú dẹ̀dẹ̀,’ ẹ̀yin àgàbàgebè, ẹ̀yin le sọ ààmì ojú ọ̀run, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò le mọ ààmì àwọn àkókò wọ̀nyí. Ìran búburú aláìgbàgbọ́ yìí ń béèrè ààmì àjèjì mélòó kàn ni ojú sánmọ̀, ṣùgbọ́n a kí yóò fún ẹnìkankan ní ààmì bí kò ṣe ààmì Jona.” Nígbà náà ni Jesu fi wọ́n sílẹ̀, ó sì bá tirẹ̀ lọ.

Read full chapter

Ààmì Jona

38 (A)Nígbà náà ni, díẹ̀ nínú àwọn Farisi àti àwọn olùkọ́ òfin wí fún pé “Olùkọ́, àwa fẹ́ rí iṣẹ́ ààmì kan lọ́dọ̀ rẹ̀”.

39 Ó sì dá wọn lóhùn wí pé “Ìran búburú àti ìran panṣágà ń béèrè ààmì; ṣùgbọ́n kò sí ààmì tí a ó fi fún un, bí kò ṣe ààmì Jona wòlíì.

Read full chapter

Ààmì ti Jona

29 (A)(B) Nígbà tí ìjọ ènìyàn sì ṣùjọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí wí pé, “Ìran búburú ni èyí: wọ́n ń wá ààmì; a kì yóò sì fi ààmì kan fún un bí kò ṣe ààmì Jona wòlíì!

Read full chapter

Bible Gateway Sponsors