Add parallel Print Page Options

Àkọsílẹ̀ ìwé ìran Jesu Kristi

Ìwé ìran Jesu Kristi, ẹni tí í ṣe ọmọ Dafidi, ọmọ Abrahamu:

Abrahamu ni baba Isaaki;

Isaaki ni baba Jakọbu;

Jakọbu ni baba Juda àti àwọn arákùnrin rẹ̀,

Juda ni baba Peresi àti Sera,

Tamari sì ni ìyá rẹ̀,

Peresi ni baba Hesroni:

Hesroni ni baba Ramu;

Ramu ni baba Amminadabu;

Amminadabu ni baba Nahiṣoni;

Nahiṣoni ni baba Salmoni;

Salmoni ni baba Boasi, Rahabu sí ni ìyá rẹ̀;

Boasi ni baba Obedi, Rutu sí ni ìyá rẹ̀;

Obedi sì ni baba Jese;

Jese ni baba Dafidi ọba.

Dafidi ni baba Solomoni, ẹni tí ìyá rẹ̀ jẹ́ aya Uriah tẹ́lẹ̀ rí.

Solomoni ni baba Rehoboamu,

Rehoboamu ni baba Abijah,

Abijah ni baba Asa,

Asa ni baba Jehoṣafati;

Jehoṣafati ni baba Jehoramu;

Jehoramu ni baba Ussiah;

Ussiah ni baba Jotamu;

Jotamu ni baba Ahaṣi;

Ahaṣi ni baba Hesekiah;

10 Hesekiah ni baba Manase;

Manase ni baba Amoni;

Amoni ni baba Josiah;

11 (A)Josiah sì ni baba Jekoniah àti àwọn arákùnrin rẹ̀ ní àkókò ìkólọ sí Babeli.

12 Lẹ́yìn ìkólọ sí Babeli:

Jekoniah ni baba Ṣealitieli;

Ṣealitieli ni baba Serubbabeli;

13 Serubbabeli ni baba Abihudi;

Abihudi ni baba Eliakimu;

Eliakimu ni baba Asori;

14 Asori ni baba Sadoku;

Sadoku ni baba Akimu;

Akimu ni baba Elihudi;

15 Elihudi ni baba Eleasari;

Eleasari ni baba Mattani;

Mattani ni baba Jakọbu;

16 Jakọbu ni baba Josẹfu, ẹni tí ń ṣe ọkọ Maria, ìyá Jesu, ẹni tí í ṣe Kristi.

17 Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo wọ́n jẹ́ ìran mẹ́rìnlá láti orí Abrahamu dé orí Dafidi, ìran mẹ́rìnlá á láti orí Dafidi títí dé ìkólọ sí Babeli, àti ìran mẹ́rìnlá láti ìkólọ títí dé orí Kristi.

Read full chapter

Nígbà tí Adamu di ẹni àádóje ọdún (130), ó bí ọmọkùnrin kan tí ó jọ ọ́, tí ó jẹ́ àwòrán ara rẹ̀, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Seti. Ọjọ́ Adamu, lẹ́yìn ìgbà tí ó bí Seti, jẹ́ ẹgbẹ̀rin ọdún (800), ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin. Àpapọ̀ ọdún tí Adamu gbé ní orí ilẹ̀ jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún-ọdún ó-lé-ọgbọ̀n (930), ó sì kú.

Nígbà tí Seti pé àrùnlélọ́gọ́rùnún ọdún (105), ó bí Enoṣi. Lẹ́yìn ìgbà tí ó bí Enoṣi, Seti sì gbé fún ẹgbẹ̀rin ó-lé-méje ọdún (807), ó sì bí àwọn; ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin. Àpapọ̀ ọdún Seti sì jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún-ọdún ó-lé-méjìlá (912), ó sì kú.

Nígbà tí Enoṣi di ẹni àádọ́rùn-ún ọdún (90) ni ó bí Kenani. 10 Lẹ́yìn tí ó bí Kenani, Enoṣi sì wà láààyè fún ẹgbẹ̀rin ọdún ó-lé-mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (815), ó sì bí àwọn ọkùnrin àti obìnrin. 11 Àpapọ̀ ọdún Enoṣi jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún-ọdún ó-lé-márùn-ún (905), ó sì kú.

12 Nígbà tí Kenani di àádọ́rin ọdún (70) ni ó bí Mahalaleli: 13 Lẹ́yìn tí ó bí Mahalaleli, Kenani wà láààyè fún òjìlélẹ́gbẹ̀rin ọdún (840), ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin. 14 Àpapọ̀ ọjọ́ Kenani jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún ó-lé-mẹ́wàá ọdún (910), ó sì kú.

15 Nígbà tí Mahalaleli pé ọmọ àrùnlélọ́gọ́ta ọdún (65) ni ó bí Jaredi. 16 Mahalaleli sì gbé fún ẹgbẹ̀rin ó-lé-ọgbọ̀n ọdún (830) lẹ́yìn ìgbà tí ó bí Jaredi, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin. 17 Àpapọ̀ iye ọdún Mahalaleli jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ̀gbẹ̀rún-ọdún-ó-dín-márùn-ún (895), ó sì kú.

18 Nígbà tí Jaredi pé ọmọ ọgọ́jọ ó-lé-méjì ọdún (162) ni ó bí Enoku. 19 Lẹ́yìn èyí, Jaredi wà láààyè fún ẹgbẹ̀rin ọdún (800) Enoku sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin. 20 Àpapọ̀ ọdún Jaredi sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún-dínméjìdínlógójì (962), ó sì kú.

21 Nígbà tí Enoku pé ọmọ ọgọ́ta ó-lé-márùn ọdún (65) ni ó bí Metusela. 22 Lẹ́yìn tí ó bí Metusela, Enoku sì bá Ọlọ́run rìn ní ọ̀ọ́dúnrún ọdún (300), ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin. 23 Àpapọ̀ ọjọ́ Enoku sì jẹ́ irínwó-dínmárùn-dínlógójì-ọdún (365). 24 (A)Enoku bá Ọlọ́run rìn; a kò sì rí i mọ́ nítorí Ọlọ́run mú un lọ.

25 Nígbà tí Metusela pé igba ó-dínmẹ́tàlá ọdún (187) ní o bí Lameki. 26 Lẹ́yìn èyí Metusela wà láààyè fún ẹgbẹ̀rìn-dínméjì-dínlógún ọdún (782), lẹ́yìn ìgbà tí ó bí Lameki, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin. 27 Àpapọ̀ ọdún Metusela jẹ́ ẹgbẹ̀rún ọdún ó-dínmọ́kànlélọ́gbọ̀n (969), ó sì kú.

28 Nígbà tí Lameki pé ọdún méjìlélọ́gọ́sàn án (182) ni ó bí ọmọkùnrin kan. 29 Ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Noa, ó sì wí pé, “Eléyìí ni yóò tù wá nínú ni iṣẹ́ àti làálàá ọwọ́ wa, nítorí ilẹ̀ tí Ọlọ́run ti fi gégùn ún.” 30 Lẹ́yìn tí ó bí Noa, Lameki gbé fún ẹgbẹ̀ta ó-dínmárùn-ún ọdún (595), ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin. 31 Àpapọ̀ ọdún Lameki sì jẹ́ ẹgbẹ̀rin ọdún ó-dínmẹ́tàlélógún (777), ó sì kú.

32 Lẹ́yìn tí Noa pé ọmọ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ọdún (500) ni ó bí Ṣemu, Hamu àti Jafeti.

Read full chapter

Ìran Ṣemu tó fi dé ti Abramu

10 Wọ̀nyí ni ìran Ṣemu.

Ọdún méjì lẹ́yìn ìkún omi, tí Ṣemu pé ọgọ́rùn-ún ọdún (100) ni ó bí Arfakṣadi. 11 Lẹ́yìn tí ó bí Arfakṣadi, Ṣemu tún wà láààyè fún ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ọdún (500), ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn.

12 Nígbà tí Arfakṣadi pé ọdún márùn-dínlógójì (35) ni ó bí Ṣela. 13 Arfakṣadi sì wà láààyè fún ọdún mẹ́tàlénírinwó (403) lẹ́yìn tí ó bí Ṣela, ó sì bí àwọn ọmọbìnrin àti àwọn ọmọkùnrin mìíràn.

14 Nígbà tí Ṣela pé ọmọ ọgbọ̀n ọdún (30) ni ó bí Eberi. 15 Ṣela sì wà láààyè fún ọdún mẹ́tàlénírinwó (403) lẹ́yìn tí ó bí Eberi tán, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn.

16 Eberi sì jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n (34), ó sì bí Pelegi. 17 Eberi sì wà láààyè fún irínwó ó-lé-ọgbọ̀n ọdún (430) lẹ́yìn tí ó bí Pelegi, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn.

18 Nígbà tí Pelegi pé ọmọ ọgbọ̀n ọdún (30) ni ó bí Reu. 19 Pelegi sì tún wà láààyè fún igba ó-lé-mẹ́sàn án ọdún (209) lẹ́yìn tí ó bí Reu, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn.

20 Nígbà tí Reu pé ọdún méjìlélọ́gbọ̀n (32) ni ó bí Serugu. 21 Reu tún wà láààyè lẹ́yìn tí ó bí Serugu fún igba ó-lé-méje ọdún (207), ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin mìíràn.

22 Nígbà tí Serugu pé ọmọ ọgbọ̀n ọdún (30) ni ó bí Nahori. 23 Serugu sì wà láààyè fún igba ọdún (200) lẹ́yìn tí ó bí Nahori, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn.

24 Nígbà tí Nahori pé ọmọ ọdún mọ́kàn-dínlọ́gbọ̀n (29), ó bí Tẹra. 25 Nahori sì wà láààyè fún ọdún mọ́kàn-dínlọ́gọ́fà (119) lẹ́yìn ìbí Tẹra, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn.

26 Lẹ́yìn tí Tẹra pé ọmọ àádọ́rin ọdún (70) ó bí Abramu, Nahori àti Harani.

Read full chapter

18 Èyí ni ìran Peresi:

Peresi ni baba Hesroni,

19 Hesroni ni baba Ramu,

Ramu ni baba Amminadabu

20 Amminadabu ni baba Nahiṣoni,

Nahiṣoni ni baba Salmoni,

21 Salmoni ni baba Boasi,

Boasi ni baba Obedi,

22 Obedi ní baba Jese,

Jese ni baba Dafidi.

Read full chapter

Ìran Adamu títí de Abrahamu

Títí dé ọmọkùnrin Noa

(A)Adamu, Seti, Enoṣi,

Kenani, Mahalaleli, Jaredi,

Enoku, Metusela, Lameki,

Noa.

Àwọn ọmọ Noa: Ṣemu, Hamu àti Jafeti.

Read full chapter

24 Ṣemu, Arfakṣadi, Ṣela,

25 Eberi, Pelegi. Reu,

26 Serugu, Nahori, Tẹra:

27 Àti Abramu (tí ń ṣe Abrahamu).

Ìdílé Abrahamu

28 Àwọn ọmọ Abrahamu: Isaaki àti Iṣmaeli.

Read full chapter

Àwọn ọmọ Israẹli

(A)Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Israẹli. Reubeni, Simeoni, Lefi, Juda, Isakari, Sebuluni, Dani, Josẹfu, Benjamini; Naftali, Gadi: àti Aṣeri.

Juda

Àwọn ọmọ Hesroni

(B)Àwọn ọmọ Juda:

Eri, Onani àti Ṣela, àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ̀nyí ni wọ́n bí fún un láti ọ̀dọ̀ arábìnrin Kenaani, ọmọbìnrin Ṣua.

Eri àkọ́bí Juda, ó sì burú ní ojú Olúwa; Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa sì pa á.

Tamari, aya ọmọbìnrin Juda, ó sì bí Peresi àti Sera sì ní ọmọ márùn-ún ní àpapọ̀.

(C)Àwọn ọmọ Peresi:

Hesroni àti Hamulu.

Àwọn ọmọ Sera:

Simri, Etani, Hemani, Kalkoli àti Dara, gbogbo wọn jẹ́ márùn-ún.

Àwọn ọmọ Karmi:

Akani, ẹni tí ó mú ìyọnu wá sórí Israẹli nípa ẹ̀ṣẹ̀ ìfibú lórí mímú ohun ìyàsọ́tọ̀.

Àwọn ọmọ Etani:

Asariah.

Àwọn ọmọ tí a bí fún Hesroni ni:

Jerahmeeli, Ramu àti Kalebu.

Láti ọ̀dọ̀ Ramu ọmọ Hesroni

10 Ramu sì ni baba Amminadabu,

àti Amminadabu baba Nahiṣoni olórí àwọn ènìyàn Juda.

11 Nahiṣoni sì ni baba Salmoni,

Salmoni ni baba Boasi,

12 Boasi baba Obedi

àti Obedi baba Jese.

13 Jese sì ni baba

Eliabu àkọ́bí rẹ̀; ọmọ ẹlẹ́kejì sì ni Abinadabu,

ẹlẹ́kẹta ni Ṣimea, 14 Ẹlẹ́kẹrin Netaneli,

ẹlẹ́karùnún Raddai, 15 ẹlẹ́kẹfà Osemu

àti ẹlẹ́keje Dafidi.

Read full chapter