A A A A A
Bible Book List

Johanu 7 Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Jesu lọ sí àjọ ìpàgọ́

Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí Jesu ń rìn ní Galili: nítorí tí kò fẹ́ rìn ní Judea, nítorí àwọn Júù ń wá a láti pa. Àjọ àwọn Júù tí í ṣe àjọ àgọ́ súnmọ́ etílé tan. Nítorí náà, àwọn arákùnrin rẹ̀ wí fún un pé, “Lọ kúrò níhìn-ín-yìí, kí o sì lọ sí Judea, kí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ pẹ̀lú lè fi iṣẹ́ rẹ hàn fún aráyé. Nítorí pé kò sí ẹnikẹ́ni tí í ṣe ohunkóhun níkọ̀kọ̀, tí òun tìkára rẹ̀ sì ń fẹ́ kí a mọ òun ní gbangba. Bí ìwọ bá ń ṣe nǹkan wọ̀nyí, fi ara rẹ hàn fún aráyé.” Nítorí pé àwọn arákùnrin rẹ̀ pàápàá kò tilẹ̀ gbà á gbọ́.

Nítorí náà ni Jesu wí fún wọn pé, “Àkókò gan an fún mi kò tí ì dé; fún ẹ̀yin, gbogbo àkókò ni ó dára fún yín. Ayé kò lè kórìíra yín; ṣùgbọ́n èmi ni ó kórìíra, nítorí tí mo jẹ́rìí gbé é pé, iṣẹ́ rẹ̀ burú. Ẹ̀yin ẹ gòkè lọ sí àjọ yìí: èmi kì yóò tí ì gòkè lọ sí àjọ yìí; nítorí tí àkókò mi kò ì tí ì dé.” Nígbà tí ó ti sọ nǹkan wọ̀nyí fún wọn tan, ó dúró ní Galili síbẹ̀.

10 Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn arákùnrin rẹ̀ gòkè lọ tan, nígbà náà ni òun sì gòkè lọ sí àjọ náà pẹ̀lú, kì í ṣe ní gbangba, ṣùgbọ́n bí ẹni pé níkọ̀kọ̀. 11 Nígbà náà ni àwọn Júù sì ń wá a kiri nígbà àjọ wí pé, “Níbo ni ó wà?”

12 Ìkùnsínú púpọ̀ sì wà láàrín àwọn ìjọ ènìyàn nítorí rẹ̀: nítorí àwọn kan wí pé, “Ènìyàn rere ní í ṣe.”

Àwọn mìíràn wí pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́, ṣùgbọ́n òun ń tan ènìyàn jẹ ni.” 13 Ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan tí ó sọ̀rọ̀ rẹ̀ ní gbangba nítorí ìbẹ̀rù àwọn Júù.

Jesu kọ́ àwọn ènìyàn

14 Nígbà tí àjọ dé àárín; Jesu gòkè lọ sí tẹmpili ó sì ń kọ́ni. 15 Ẹnu sì ya àwọn Júù, wọ́n wí pé, “Ọkùnrin yìí ti ṣe mọ ìwé, nígbà tí kò kọ́ ẹ̀kọ́?”

16 Jesu dáhùn, ó sì wí pé, “Ẹ̀kọ́ mi kì í ṣe tèmi, bí kò ṣe ti ẹni tí ó rán mi. 17 Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀ yóò mọ̀ ní ti ẹ̀kọ́ náà, bí ìbá ṣe ti Ọlọ́run, tàbí bí èmi bá sọ ti ara mi. 18 Ẹni tí ń sọ ti ara rẹ̀ ń wá ògo ara rẹ̀: ṣùgbọ́n ẹni tí ń wá ògo ẹni tí ó rán an, òun ni olóòtítọ́, kò sì sí àìṣòdodo nínú rẹ̀. 19 Mose kò ha fi òfin fún yín, kò sí ẹnikẹ́ni nínú yín tí ó pa òfin náà mọ́? Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń wá ọ̀nà láti pa mí?”

20 Ìjọ ènìyàn dáhùn, wọ́n sì wí pé, “Ìwọ ní ẹ̀mí èṣù: Ta ni ń wá ọ̀nà láti pa ọ́?”

21 Jesu dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Kìkì iṣẹ́ ààmì kan ni mo ṣe, ẹnu sì ya gbogbo yín. 22 Síbẹ̀, nítorí pé Mose fi ìkọlà fún yín (kò tilẹ̀ kúkú wá láti ọ̀dọ̀ Mose bí kò ṣe láti ọ̀dọ̀ àwọn baba ńlá yín); nítorí náà ẹ sì ń kọ ènìyàn ní ilà ní ọjọ́ ìsinmi. 23 Bí ènìyàn bá ń gba ìkọlà ní ọjọ́ ìsinmi, kí a má ba à rú òfin Mose, ẹ ha ti ṣe ń bínú sí mi, nítorí mo mú ènìyàn kan láradá ní ọjọ́ ìsinmi? 24 Ẹ má ṣe ìdájọ́ nípa ti ara, ṣùgbọ́n ẹ máa ṣe ìdájọ́ òdodo.”

Ṣé Jesu ni Kristi?

25 Nígbà náà ni àwọn kan nínú àwọn ará Jerusalẹmu wí pé, “ẹni tí wọ́n ń wá ọ̀nà láti pa kọ́ yìí? 26 Sì wò ó, ó ń sọ̀rọ̀ ní gbangba, wọn kò sì wí nǹkan kan sí i. Àwọn olórí ha mọ̀ nítòótọ́ pé, èyí ni Kristi náà? 27 Ṣùgbọ́n àwa mọ ibi tí ọkùnrin yí gbé ti wá: ṣùgbọ́n nígbà tí Kristi bá dé, kò sí ẹni tí yóò mọ ibi tí ó gbé ti wá.”

28 Nígbà náà ni Jesu kígbe ní tẹmpili bí ó ti ń kọ́ni, wí pé, “Ẹ̀yin mọ̀ mí, ẹ sì mọ ibi tí mo ti wá: èmi kò sì wá fún ara mi, ṣùgbọ́n olóòtítọ́ ni ẹni tí ó rán mi, ẹni tí ẹ̀yin kò mọ̀. 29 Ṣùgbọ́n èmi mọ̀ ọ́n: nítorí pé lọ́dọ̀ rẹ̀ ni mo ti wá, òun ni ó rán mi.”

30 Nítorí náà wọ́n ń wá ọ̀nà à ti mú un: ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan tí ó gbé ọwọ́ lé e, nítorí tí wákàtí rẹ̀ kò tí ì dé. 31 Ọ̀pọ̀ nínú ìjọ ènìyàn sì gbà á gbọ́, wọ́n sì wí pé, “Nígbà tí Kristi náà bá dé, yóò ha ṣe iṣẹ́ ààmì jù wọ̀nyí, tí ọkùnrin yìí ti ṣe lọ?”

32 Àwọn Farisi gbọ́ pé, ìjọ ènìyàn ń sọ nǹkan wọ̀nyí lábẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀; àwọn Farisi àti àwọn olórí àlùfáà sì rán àwọn oníṣẹ́ lọ láti mú un.

33 Nítorí náà Jesu wí fún wọn pé, “Níwọ́n ìgbà díẹ̀ ni èmi yóò wà pẹ̀lú yín, èmi yóò lọ sí ọ̀dọ̀ ẹni tí ó rán mi. 34 Ẹ̀yin yóò wá mi, ẹ̀yin kì yóò sì rí mi: àti ibi tí èmi bá wà, ẹ̀yin kì yóò le wà.”

35 Nítorí náà ni àwọn Júù ń bá ara wọn sọ pé, “Níbo ni ọkùnrin yìí yóò gbé lọ tí àwa kì yóò fi rí i? Yóò ha lọ sí àárín àwọn Helleni tí wọ́n fọ́n káàkiri, kí ó sì máa kọ́ àwọn Helleni bí. 36 Ọ̀rọ̀ kín ni èyí tí ó sọ yìí, ẹ̀yin yóò wá mi, ẹ kì yóò sì rí mi, àti ibi tí èmi bá wà ẹ̀yin kì yóò le wà?”

37 Lọ́jọ́ tó kẹ́yìn, tí í ṣe ọjọ́ ńlá àjọ, Jesu dúró, ó sì kígbe wí pé, “Bí òǹgbẹ bá ń gbẹ ẹnikẹ́ni, kí ó tọ̀ mí wá, kí ó sì mu. 38 Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà mí gbọ́ gẹ́gẹ́ bí ìwé mímọ́ ti wí, láti inú rẹ̀ ni odò omi ìyè yóò ti máa sàn jáde wá.” 39 (Ṣùgbọ́n ó sọ èyí ní ti ẹ̀mí, tí àwọn tí ó gbà á gbọ́ ń bọ̀ wá gbà: nítorí a kò tí ì fi ẹ̀mí mímọ́ fún ni; nítorí tí a kò tí ì ṣe Jesu lógo.)

40 Nítorí náà nígbà tí ọ̀pọ̀ nínú ìjọ ènìyàn gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, wọ́n wí pé, “Lóòótọ́ èyí ni wòlíì náà.”

41 Àwọn mìíràn wí pé, “Èyí ni Kristi náà.”

Ṣùgbọ́n àwọn kan wí pé kínla, “Kristi yóò ha ti Galili wá bí? 42 Ìwé mímọ́ kò ha wí pé, Kristi yóò ti inú irú-ọmọ Dafidi wá, àti Bẹtilẹhẹmu, ìlú tí Dafidi ti wá?” 43 Bẹ́ẹ̀ ni ìyapa wà láàrín ìjọ ènìyàn nítorí rẹ̀. 44 Àwọn mìíràn nínú wọn sì fẹ́ láti mú un; ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan tí ó gbé ọwọ́ lé e.

Àìgbàgbọ́ àwọn adarí Júù

45 Ní ìparí, àwọn ẹ̀ṣọ́ tẹmpili padà tọ àwọn olórí àlùfáà àti àwọn Farisi lọ, wọ́n sì wí fún wọn pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin kò fi mú un wá?”

46 Àwọn ẹ̀ṣọ́ dáhùn wí pé, “Kò sí ẹni tí ó tí ì sọ̀rọ̀ bí ọkùnrin yìí rí!”

47 Nítorí náà àwọn Farisi dá wọn lóhùn pé, “A ha tan ẹ̀yin jẹ pẹ̀lú bí? 48 Ǹjẹ́ nínú àwọn ìjòyè, tàbí àwọn Farisi ti gbà á gbọ́ bí? 49 Ṣùgbọ́n ìjọ ènìyàn yìí, tí ko mọ òfin di ẹni ìfibú.”

50 Nikodemu ẹni tí ó tọ Jesu wá lóru rí, tí ó sì jẹ́ ọ̀kan nínú wọn sì sọ fún wọn pé, 51 “Òfin wa ha ń ṣe ìdájọ́ ènìyàn kí ó tó gbọ́ ti ẹnu rẹ̀ àti kí ó tó mọ ohun tí ó ṣe bí?”

52 Wọ́n dáhùn wọ́n sì wí fún un pé, “Ìwọ pẹ̀lú wá láti Galili bí? Wá kiri, kí o sì wò nítorí kò sí wòlíì kan tí ó ti Galili dìde.”

53 Wọ́n sì lọ olúkúlùkù sí ilé rẹ̀.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.

  Back

1 of 1

You'll get this book and many others when you join Bible Gateway Plus. Learn more

Viewing of
Cross references
Footnotes