A A A A A
Bible Book List

2 Kọrinti 10 Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Paulu gbèjà iṣẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀

10 Ṣùgbọ́n èmi Paulu fúnra mi fi inú tútù àti ìwà pẹ̀lẹ́ Kristi bẹ̀ yín, èmi ẹni ìrẹ̀lẹ̀ lójú yín nígbà tí mo wà láàrín yín, ṣùgbọ́n nígbà tí èmi kò sí, mo di ẹni ìgboyà sí yín. Ṣùgbọ́n èmi bẹ̀ yín pé nígbà tí mo wà láàrín yín, kí èmi ba à lè lo ìgboyà pẹ̀lú ìgbẹ́kẹ̀lé náà, eléyìí tí mo ti fọkàn sí láti fi dojúkọ àwọn kan, ti ń funra sí wa bí ẹni tí ń rìn nípa ìlànà ti ayé yìí. Nítorí pé, bí àwa tilẹ̀ n gbé nínú ayé, ṣùgbọ́n àwa kò jagun nípa ti ara. Nítorí ohun ìjà wa kì í ṣe ti ara, ṣùgbọ́n ó lágbára nínú Ọlọ́run láti wó ibi gíga palẹ̀. Àwa ń sọ gbogbo èrò àti gbogbo ohun gíga ti ń gbe ara rẹ̀ ga sí ìmọ̀ Ọlọ́run kalẹ̀, àwa sì ń di gbogbo èrò ní ìgbèkùn wá sí ìtẹríba fún Kristi. Àwa sì ti murá tan láti jẹ gbogbo àìgbọ́ràn ní yà, nígbà tí ìgbọ́ràn yín bá pé.

Ẹ̀yin sì ń wo nǹkan gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti fihàn lóde. Bí ẹnikẹ́ni bá ní ìgboyà nínú ara rẹ̀, ti Kristi ni òun, kí ó tún rò lẹ́ẹ̀kan si pé, bí òun ti jẹ́ ti Kristi, gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni àwa pẹ̀lú jẹ́ ti Kristi. Nítorí bí mo tilẹ̀ ń ṣògo bí ó ti wù mi nítorí agbára, tí Olúwa ti fi fún wá fún ìdàgbàsókè, dípò fífà yín ṣubú, ojú kí yóò tì mí. Kí ó má ṣe dàbí ẹni pé èmi ń fi ìwé kíkọ dẹ́rùbà yín. 10 Nítorí wọ́n wí pé, “Ìwé rẹ wúwo, wọn sì lágbára; ṣùgbọ́n ní ti ara ìrísí rẹ̀ jẹ aláìlera, ọ̀rọ̀ rẹ kò níláárí.” 11 Kí irú ènìyàn bẹ́ẹ̀ mọ̀ pé, irú ẹni tí àwa jẹ́ nínú ọ̀rọ̀ nípa ìwé kíkọ nígbà tí àwa kò sí, irú ẹni bẹ́ẹ̀ ni àwa sì jẹ́ nínú iṣẹ́ pẹ̀lú nígbà ti àwa bá wà.

12 Nítorí pé àwa kò dáṣà láti ka ara wa mọ́, tàbí láti fi ara wa wé àwọn mìíràn nínú wọn tí ń yin ara wọn; ṣùgbọ́n àwọn fúnrawọn jẹ́ aláìlóye bí wọn ti ń fi ara wọn díwọ̀n ara wọ́n, tí wọ́n sì ń fi ara wọn wé ara wọn. 13 Ṣùgbọ́n àwa kò ṣògo rékọjá ààlà wa, ṣùgbọ́n nípa ààlà ìwọ̀n tí Ọlọ́run ti pín fún wa, èyí tí ó mú kí ó ṣe é ṣe láti dé ọ̀dọ̀ yín. 14 Nítorí àwa kò nawọ́ wa rékọjá rárá, bí ẹni pé àwa kò dé ọ̀dọ̀ yín: nítorí àwa tilẹ̀ dé ọ̀dọ̀ yín pẹ̀lú nínú ìhìnrere Kristi. 15 Àwa kò ṣògo rékọjá ààlà wa, èyí nì, lórí iṣẹ́ ẹlòmíràn, ṣùgbọ́n àwa ní ìrètí pé, bí ìgbàgbọ́ yín ti ń dàgbà sí i, gẹ́gẹ́ bí ààlà wa, àwa ó dí gbígbéga lọ́dọ̀ yín sí i lọ́pọ̀lọpọ̀. 16 Kí a bá à lè wàásù ìhìnrere ní àwọn ìlú tí ń bẹ níwájú yín, kí a má sì ṣògo nínú ààlà ẹlòmíràn nípa ohun tí ó wà ní àrọ́wọ́tó. 17 “Ṣùgbọ́n jẹ́ kí ẹni tí ó bá ń ṣògo, kí ó máa ṣògo nínú Olúwa.” 18 Nítorí kì í ṣe ẹni tí ń yin ara rẹ̀ ni ó ní ìtẹ́wọ́gbà, bí kò ṣe ẹni tí Olúwa bá yìn.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.

2 Corinthians 10 New International Version (NIV)

Paul’s Defense of His Ministry

10 By the humility and gentleness of Christ, I appeal to you—I, Paul, who am “timid” when face to face with you, but “bold” toward you when away! I beg you that when I come I may not have to be as bold as I expect to be toward some people who think that we live by the standards of this world. For though we live in the world, we do not wage war as the world does. The weapons we fight with are not the weapons of the world. On the contrary, they have divine power to demolish strongholds. We demolish arguments and every pretension that sets itself up against the knowledge of God, and we take captive every thought to make it obedient to Christ. And we will be ready to punish every act of disobedience, once your obedience is complete.

You are judging by appearances.[a] If anyone is confident that they belong to Christ, they should consider again that we belong to Christ just as much as they do. So even if I boast somewhat freely about the authority the Lord gave us for building you up rather than tearing you down, I will not be ashamed of it. I do not want to seem to be trying to frighten you with my letters. 10 For some say, “His letters are weighty and forceful, but in person he is unimpressive and his speaking amounts to nothing.” 11 Such people should realize that what we are in our letters when we are absent, we will be in our actions when we are present.

12 We do not dare to classify or compare ourselves with some who commend themselves. When they measure themselves by themselves and compare themselves with themselves, they are not wise. 13 We, however, will not boast beyond proper limits, but will confine our boasting to the sphere of service God himself has assigned to us, a sphere that also includes you. 14 We are not going too far in our boasting, as would be the case if we had not come to you, for we did get as far as you with the gospel of Christ. 15 Neither do we go beyond our limits by boasting of work done by others. Our hope is that, as your faith continues to grow, our sphere of activity among you will greatly expand, 16 so that we can preach the gospel in the regions beyond you. For we do not want to boast about work already done in someone else’s territory. 17 But, “Let the one who boasts boast in the Lord.”[b] 18 For it is not the one who commends himself who is approved, but the one whom the Lord commends.

Footnotes:

  1. 2 Corinthians 10:7 Or Look at the obvious facts
  2. 2 Corinthians 10:17 Jer. 9:24
New International Version (NIV)

Holy Bible, New International Version®, NIV® Copyright ©1973, 1978, 1984, 2011 by Biblica, Inc.® Used by permission. All rights reserved worldwide.

Viewing of
Cross references
Footnotes