A A A A A
Bible Book List

1 Kọrinti 12 Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́

12 Ní ti Ẹ̀mí Mímọ́ ẹ̀yin ará, kò yẹ́ kí ẹ jẹ́ òpè. Ẹ̀yin kò mọ̀ pé nígbà tí ẹ̀yin jẹ́ kèfèrí, a fà yín lọ sọ́dọ̀ àwọn odi òrìṣà. Nítorí náà, èmí ń sọ fún un yín pé kò sí ẹni ti ń sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ Ẹ̀mí Ọlọ́run tí ó lè wí pé, “Ẹni ìfibú ni Jesu,” àti pé kò sí ẹni tí ó lè sọ pé, “Olúwa ni Jesu,” bí kò ṣe nípasẹ̀ Ẹ̀mí mímọ́.

Ǹjẹ́ onírúurú ẹ̀bùn ni ó wà, ṣùgbọ́n Ẹ̀mí kan náà ni o ń pín wọn. Onírúurú iṣẹ́ ìránṣẹ́ ni ó sì wà, ṣùgbọ́n Ọlọ́run kan náà sì ni. Onírúurú iṣẹ́ ìránṣẹ́ ni ó sì wà, ṣùgbọ́n Ọlọ́run kan náà ni ẹni tí ń ṣiṣẹ́ gbogbo wọn nínú gbogbo wọn.

Ṣùgbọ́n à ń fi ẹ̀bùn Ẹ̀mí fún olúkúlùkù ènìyàn láti fi jèrè. Ẹ̀mí Mímọ́ lè fún ẹnìkan ní ọgbọ́n láti lè fún ènìyàn nímọ̀ràn, ẹlòmíràn ní ẹ̀bùn láti sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ìmọ̀ ńlá. Láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ kan náà ni èyí ti wá. Ó fi ẹ̀bùn ìgbàgbọ́ fún ẹlòmíràn, ẹlòmíràn ló sì fi agbára ìwòsàn fún nípa Ẹ̀mí Mímọ́ kan náà. 10 Ó fi agbára fún àwọn mìíràn láti ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu. Ó fún àwọn mìíràn lágbára láti sọ àsọtẹ́lẹ̀ àti láti wàásù pẹ̀lú ìmísí. Bákan náà ló fún àwọn kan lẹ́bùn láti mọ ìyàtọ̀ láàrín àwọn ẹ̀mí. Ó fún àwọn ẹlòmíràn ní ẹ̀bùn àti agbára láti lè sọ èdè tí wọn kò mọ̀. Bákan náà ó fún àwọn ẹlòmíràn lágbára láti mọ̀ àti láti túmọ̀ èdè tí wọn kò gbọ́ rí. 11 Àní, Ẹ̀mí kan ṣoṣo ní ń fún ni ní gbogbo ẹ̀bùn àti agbára wọ̀nyí. Òun ni ẹni tí ń ṣe ìpinnu ẹ̀bùn tí ó yẹ láti fún ẹnìkọ̀ọ̀kan.

12 Ara jẹ́ ọ̀kan tí ó ní àwọn ẹ̀yà púpọ̀, ṣùgbọ́n gbogbo àwọn ẹ̀yà ara tí ó pọ̀ wọ̀nyí ni ó papọ̀ láti jẹ́ ara kan ṣoṣo. Bákan náà ni ó rí pẹ̀lú ara Kristi tí í ṣe ìjọ. 13 Nítorí pé nínú Ẹ̀mí kan ní a ti bamitiisi gbogbo wa sínú ara kan, ìbá à ṣe Júù, ìbá à ṣe Giriki, ìbá à ṣe ẹrú, ìbá à ṣe òmìnira, gbogbo wa ni a mu nínú Ẹ̀mí Mímọ́ kan náà. 14 Bẹ́ẹ̀ ni, ara, kì í ṣe ẹ̀yà kan ṣoṣo bí kò ṣe púpọ̀.

15 Tí ẹsẹ̀ bá wí pé, “Nítorí èmi kì í ṣe ọwọ́, èmi kì í ṣe ti ara,” èyí kò wí pé kì í ṣe ọ̀kan lára nínú ẹ̀yà ara. 16 Bí etí bá wí pé, “Nítorí èmi kì í ṣe ojú, èmi kì í ṣe apá kan ara,” èyí kò le mú kí ó má jẹ́ apá kan ara mọ́ 17 Bí gbogbo ara bá jẹ́ ojú, níbo ni ìgbọ́ran ìbá gbé wà? Bí gbogbo ara bá jẹ́ etí, níbo ni ìgbóórùn ìbá gbé wà? 18 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ti fi àwọn ẹ̀yà ara si ara wa, ó sí fi ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan sí ibi tí ó fẹ́ kí ó wà. 19 Bí gbogbo wọn bá sì jẹ́ ọ̀kan ṣoṣo nínú ẹ̀yà ara, níbo ni ara yóò gbé wà. 20 Ọlọ́run dá ẹ̀yà ara púpọ̀, ṣùgbọ́n ara kan ṣoṣo ni.

21 Bí ó tí rí yìí, ojú kò lè sọ fún ọwọ́ pé, “Èmi kò nílò rẹ.” Bẹ́ẹ̀ ni orí kò le sọ fún ẹsẹ̀ pé, “Èmi kò nílò rẹ.” 22 Àwọn ẹ̀yà ara tí ó dàbí ẹni pé wọ́n ṣe aláìlágbára jùlọ, tí ó dàbí ẹni pé kò ṣe pàtàkì rárá, àwọn gan an ni a kò le ṣe aláìnílò. 23 Bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yà ara tí a rò pé kò lọ́lá rárá ni àwa ń fi ọlá fún jùlọ. Àwọn ẹ̀yà ara tí a rò pé ko yẹ rárá ni àwa ń fi si ipò ọlá ẹ̀yẹ tí ó ga jùlọ. 24 Nítorí pé àwọn ibi tí ó ní ẹ̀yẹ ní ara wa kò nílò ìtọ́jú ọ̀tọ̀. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ti pa gbogbo ẹ̀yà ara pọ̀ ṣọ̀kan lọ́nà kan, ó sì ti fi ẹ̀yẹ tó ga jùlọ fún ibi tí ó ṣe aláìní. 25 Kí ó má ṣe sí ìyàtọ̀ nínú ara, ṣùgbọ́n kí àwọn ẹ̀yà ara le máa jẹ́ olùrànlọ́wọ́ fún ara wọn. 26 Bí ẹ̀yà ara kan bá ń jìyà, gbogbo àwọn ẹ̀yà ara ìyókù a máa bá a pín nínú ìyà náà. Tí a bá sì bu ọlá fún ẹ̀yà ara kan, gbogbo ẹ̀yà ara ìyókù a máa bá a yọ̀.

27 Gbogbo yín jẹ́ ara Kristi, ẹnìkọ̀ọ̀kan yín sì jẹ́ ẹ̀yà ara ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nínú ara Kristi. 28 Ọlọ́run sì gbé àwọn mìíràn kalẹ̀ nínú ìjọ, èkínní àwọn aposteli, èkejì àwọn wòlíì, ẹ̀kẹta àwọn olùkọ́ni, lẹ́yìn náà, àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ìyanu, lẹ́yìn náà àwọn tí ó ní ẹ̀bùn ìmúláradá, àwọn olùrànlọ́wọ́ àti àwọn agbani nímọ̀ràn, àwọn tí ń sọ onírúurú èdè. 29 Ǹjẹ́ gbogbo ènìyàn ni ó jẹ́ aposteli bi? Tàbí gbogbo ènìyàn ni wòlíì bí? Ṣe gbogbo ènìyàn ní olùkọ́ni? Ṣé gbogbo ènìyàn ló ní agbára láti ṣe iṣẹ́ ìyanu bí? 30 Ṣé gbogbo ènìyàn ló lè wonisàn bí? Rárá. Ǹjẹ́ gbogbo wa ni Ọlọ́run fún ní ẹ̀bùn láti le sọ̀rọ̀ ní èdè tí a kò ì tí ì gbọ́ rí bí? Ṣé ẹnikẹ́ni ló lè túmọ̀ èdè tí wọ́n sọ tí kò sì yé àwọn ènìyàn bí? 31 Ṣùgbọ́n, ẹ máa fi ìtara ṣàfẹ́rí ẹ̀bùn ti ó tóbi jù.

Síbẹ̀ èmi o fi ọ̀nà kan tí ó tayọ rékọjá hàn yín.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.

  Back

1 of 1

You'll get this book and many others when you join Bible Gateway Plus. Learn more

Viewing of
Cross references
Footnotes