
Ìfihàn 11 Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)Àwọn ẹlẹ́rìí méjì11 A sì fi ìfèéfèé kan fún mi tí o dàbí ọ̀pá-ìwọ̀n: ẹnìkan sì wí pé, “Dìde, wọn tẹmpili Ọlọ́run, àti pẹpẹ, àti àwọn tí ń sìn nínú rẹ̀. 2 Sì fi àgbàlá tí ń bẹ lóde tẹmpili sílẹ̀, má sì ṣe wọ́n ọ́n; nítorí tí a fi fún àwọn aláìkọlà: ìlú mímọ́ náà ni wọn ó sì tẹ̀ mọ́lẹ̀ ní oṣù méjìlélógójì. 3 Èmi ó sì yọ̀ǹda fún àwọn ẹlẹ́rìí mi méjèèje, wọn ó sì sọtẹ́lẹ̀ fún ẹgbẹ̀fà ọjọ́ ó-lé-ọgọ́ta nínú aṣọ ọ̀fọ̀.” 4 Wọ̀nyí ni igi olifi méjì náà, àti ọ̀pá fìtílà méjì náà tí ń dúró níwájú Olúwa ayé. 5 Bí ẹnikẹ́ni bá sì fẹ́ pa wọn lára, iná ó ti ẹnu wọn jáde, a sì pa àwọn ọ̀tá wọn run: báyìí ni a ó sì pa ẹnikẹ́ni tí ó ba ń fẹ́ pa wọn lára run. 6 Àwọn wọ̀nyí ni ó ni agbára láti sé ọ̀run, tí òjò kò fi lè rọ̀ ni ọjọ́ àsọtẹ́lẹ̀ wọn: Wọ́n sì ní agbára lórí omi láti sọ wọn di ẹ̀jẹ̀, àti láti fi onírúurú àjàkálẹ̀-ààrùn kọlu ayé, nígbàkúgbà tí wọ́n bá fẹ́. 7 Nígbà tí wọn bá sì ti parí ẹ̀rí wọn, ẹranko tí o ń tí inú ọ̀gbun gòkè wá yóò bá wọn jagun, yóò sì ṣẹ́gun wọn, yóò sì pa wọ́n. 8 Òkú wọn yóò sì wà ni ìgboro ìlú ńlá náà tí a ń pè ní Sodomu àti Ejibiti nípa ti ẹ̀mí, níbi tí a gbé kan Olúwa wọ́n mọ́ àgbélébùú. 9 Fún ọjọ́ mẹ́ta àti ààbọ̀ ni àwọn ènìyàn nínú ènìyàn gbogbo àti ẹ̀yà, àti èdè, àti orílẹ̀, wo òkú wọn, wọn kò si jẹ kì a gbé òkú wọn sínú ibojì. 10 Àti àwọn tí o ń gbé orí ilẹ̀ ayé yóò sì yọ̀ lé wọn lórí, wọn yóò sì ṣe àríyá, wọn ó sì ta ara wọn lọ́rẹ; nítorí tí àwọn wòlíì méjèèjì yìí dá àwọn tí o ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé lóró. 11 Àti lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta àti ààbọ̀ náà, ẹ̀mí ìyè láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá wọ inú wọn, wọn sì dìde dúró ni ẹsẹ̀ wọn; ẹ̀rù ńlá sì ba àwọn tí o rí wọn. 12 Wọn sì gbọ́ ohùn ńlá kan láti ọ̀run wá ń wí fún wọn pé, “Ẹ gòkè wá ìhín!” Wọn sì gòkè lọ sí ọ̀run nínú ìkùùkuu àwọsánmọ̀; lójú àwọn ọ̀tá wọn. 13 Ní wákàtí náà omìmì-ilẹ̀ ńlá kan sì mì, ìdámẹ́wàá ìlú náà sì wó, àti nínú omìmì-ilẹ̀ náà ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin ènìyàn ní a pa; ẹ̀rù sì ba àwọn ìyókù, wọn sì fi ògo fún Ọlọ́run ọ̀run. 14 Ègbé kejì kọjá; sì kíyèsi i, ègbé kẹta sì ń bọ̀ wá kánkán. Ìpè méje15 Angẹli keje sì fọn ìpè; a sì gbọ́ ohùn ńlá láti ọ̀run, wí pé, “Ìjọba ayé di ti Olúwa wá, àti tí Kristi rẹ̀; 16 Àwọn àgbà mẹ́rìnlélógún náà tí wọn jókòó níwájú Ọlọ́run lórí ìtẹ́ wọn, dojúbolẹ̀, wọn sì sin Ọlọ́run, 17 wí pé: “Àwa fi ọpẹ́ fún ọ, Olúwa Ọlọ́run, Olódùmarè, 19 A sì ṣí tẹmpili Ọlọ́run sílẹ̀ ní ọ̀run, a sì ri àpótí májẹ̀mú nínú tẹmpili rẹ̀. Mọ̀nàmọ́ná sì kọ, a sì gbọ́ ohùn, àrá sì sán, ilẹ̀ sì mi, yìnyín ńlá sì bọ́.
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO) Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide. |